MỌ̀RÌWÒ Ń Ṣ’Ẹ̀SỌ́ NÍNÚ ÌGBÁGÓ. PẸ̀LÚ Ẹ̀BÙ Ẹ̀YÍN TÓ BÁ ỌRỌ̀ AJÉ ILẸ̀ YÌÍ, SÍBẸ̀, ṢÈYÍ MÁKINDÉ TÚN Ń ṢE BẸBẸ

MỌ̀RÌWÒ Ń Ṣ’Ẹ̀SỌ́ NÍNÚ ÌGBÁGÓ. PẸ̀LÚ Ẹ̀BÙ Ẹ̀YÍN TÓ BÁ ỌRỌ̀ AJÉ ILẸ̀ YÌÍ, SÍBẸ̀, ṢÈYÍ MÁKINDÉ TÚN Ń ṢE BẸBẸ…!

By Aiyelabegan Baba Awo, a Member of the GSM Advocates

Ahun ń gbénú páká yọrí,
Ògòǹgò ń gbìyànjú gbórí àkìtàn sọrọ̀,
Ìgbín ń gbìyànjú, ó ń ṣọlá nínú ìkarahun,
Ìran àwọn èèrùn ń fìforítì gbágìyàn sọrọ̀.

Ọ̀tọ̀ làá jẹ̀pà,
Ọ̀tọ̀ làá jẹ̀ ‘mumu,
Ọ̀tọ̀ nifin,
Ọ̀tọ̀ nipa,
Láwùjọ obì àwọn Gómìnà lórílẹ̀ èdè yìí,
Òfùà Ṣèyí Mákindé, ọ̀tọ̀ ló wà!

Bí pápá ń jó lóko, mọ̀jàlà á délé sòfófó,
Ìràwè ní í ṣàpèjúwe ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lẹ́gàn,
Aláwọ̀ méje ni ń ṣe ‘kéde òjò tí kò ní rọ̀ mọ́,
Àyà hẹ̀rìmọ̀ ní í ṣafihan akọni òmìrán,
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ ńlá la fi í m’aya m’ọmọ ọdẹ,
Odó iyán ní í jùwe ìyàwó àgbẹ̀ kùàbà lábà!

Bí ohun gbogbo ṣe le koko tó nira,
Tí ara ń ro okùn ọrọ̀ ajé,
Tí ara kò rọ adìẹ ìnájà gbogbo nílẹ̀ yìí
Tí tàgbà tọmọdé ń já lanba láti yán an yọ,
Tí tarúgbó tomidan ilẹ̀ yìí ń pọ̀sẹ̀sẹ̀ láti borí làlúrí sànmọ́nì,
Ní ẹlẹ́yìnjú àánú ọmọ ‘Látúbọ̀sún bá dìde wùyà!
Ó ní lọ́rọ̀ afẹ́fẹ́,ọya ni ká bi,
Lọ́rọ̀ òjò, ká bi Ṣàngó léèrè,
Ìgbàyégbádùn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́,
Ojúṣe òun ọmọ Májọlágbé ni!

Ló bá gbètò kan àrà ọ̀tọ̀ kalẹ̀,
SÉFÀ(SAFER) ló pe ètò ọ̀hún,
ó ló di dandan kí gbogbo ọmọ tòun tolùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ó wà nídẹ̀kùn.
Ètò oúnjẹ fún àwọn ìdílé tí kò rọ́wọ́ họrí jùlọ ní gbogbo ẹkùn ilẹ̀ yìí làkọ́kọ́
Ó ṣètò owó ribiribi fún ẹka ètò ìlera,
Ó gbówó nlá kalẹ̀ fáwọn àgbẹ̀ k’írè oko lè sùnwá bọ̀,
Ètò ẹ̀yàwó f’áwọn ìṣòwò
Àní kí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ yìí lè rú gọ́gọ́,
Bẹ́ẹ̀ ló tún yawó fún ètò ìlera,
Ìpèsè ọkọ̀ ọ̀fẹ́ làkọ́kọ́, kó tó wá ṣètò owó ọkọ̀ tí kò gunpá fún gbogbo arìnrìnàjò nílùúsílùú nípìnlẹ̀ yìí.

Ètò owó ìrànwọ́ (wage Award) fún gbogbo òṣìṣẹ́ àtòsìsẹ́ fẹ̀yìntì ìpínlẹ̀ yìí tún ni àrà kàsíàrà!
Owó ọ̀hún ò sì tẹ̀tì,
Àní kò tẹ̀tì láti òsù mẹ́fà títí di àsìkò yìí rárá,
Èyí tó ń jẹ́ kí iṣẹ́ ó lọ geerege!

Nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti Mákindé,
Àwọn àgbẹ̀ wà SÉFÀ(SAFER),
Àwọn oníṣòwò wà SÉFÀ (SAFER),
Àwọn òṣìṣẹ́ àtòsìsẹ́ fẹ̀yìntì wà SÉFÀ (SAFER),
Ètò ìlera wà SÉFÀ (SAFER),
Kódà SÉFÀ(SAFER) ni gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ wà!

Ṣèyí tún pèsè ààyè oorun, oúnjẹ, àti ètò ìlera ọ̀fẹ́,
Àní fáwọ̀n tí làlúrí dé bá nínú ìjàm̀bá Ìbúgbàmù àbaadì ní Bódìjà,
Títí dàsìkò yìí, lórí ọ̀rọ̀ wọn
Ọmọ Mákindé ó jẹ́ ó rẹ̀ un,
Ó ní ọ̀rán tó bá bá àwòrò ti kan irúnmọlẹ̀ lábùkù!

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, Ayélabẹ́gàn Àlàó,
A dúpẹ́ pé a ò bẹ kanlékanlé lásọ rán,
A ò bẹ bíríkìlà nílé kùn,
A ò bẹ onígbàjámọ̀ pé kó bá wa túnlẹ̀kùn tó bàjẹ́ ṣe,
Nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́,
Ìka tó tọ́ símú la fi remú,
Aláàánú la yàn sípò àtàtà,
Olúwa ló Ṣèyí fún wa l’Ọ́yọ̀ọ́,
A mọ̀n ọ́n lóore o……!

© Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Abbas,
Ọ̀kan gbòógì nínú ẹgbẹ́ GSM advocate,
Ìwọ̀ Oòrùn Ọ̀yọ́,
Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

08134856062

Spread the love

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Open chat
Hello
Can we help you?